2 Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣùàti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì,ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀.
3 Láti orí àwọn omi ńláni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wáìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè,òun sì ti di ibùjókòó ọjà fúnàwọn orílẹ̀ èdè.
4 Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọàní ìwọ ilé-ààbò ti òkun,nítorí òkun ti sọ̀rọ̀:“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ ríÈmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrintàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
5 Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Éjíbítì,wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípaìròyìn láti Tírè.
6 Kọjá wá sí Táṣíṣì;pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
7 Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyáa yín,ògbólógbòò ìlú náà,èyí tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọláti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
8 Ta ló gbérò èyí sí Tírè,ìlú aládé,àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládétí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míkání orílẹ̀ ayé?