3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapátaa ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá,ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
5 àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;wọ́n ti pa àwọn òfin runwọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànàwọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora.
8 Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúróayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
9 Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.