Àìsáyà 25:5-11 BMY

5 àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà.O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

6 Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèṣèàṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnìtí ó gbámúṣé.

7 Ní orí òkè yìí ni yóò parunaṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀;

8 Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù,kúrò ní ojúu gbogbo wọn;Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúròní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un rẹ̀, òun sì gbà wá là.Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú un wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

10 Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìíṣùgbọ́n a ó tẹ Móábù mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀;gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11 Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀jáde láti lúwẹ̀ẹ́.Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn.