17 Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọtí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ Olúwa.
18 Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìroraṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.
19 Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyèara wọn yóò dìde.Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.
20 Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọkí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín,ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá.
21 Kíyèsíì, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé níìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn.Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀,kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.