5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹṣẹó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6 Ẹṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ẹṣẹ̀ aninilára n nì,ipaṣẹ̀ àwọn òtòsì.
7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́júÌwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nààwọn olódodo kúnná.
8 Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹàwa dúró dè ọ́;orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹàwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayéàwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkàwọn kò kọ́ láti ṣòdodo;kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́ntẹ̀ṣíwájú láti máa ṣe ibiwọn kò sì ka ọlá ńlá Olúwa sí.
11 Olúwa, ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókèṣùgbọ́n àwọn kò rí i.Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹkí ojú kí ó tì wọ́n;jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọnọ̀ta rẹ jó wọn run.