14 Olúwa dojú ẹjọ́ kọàwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.“Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15 Kín ni èro yín láti máa run àwọnènìyàn mi túútúútí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?”ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
16 Olúwa wí pé,“Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga,wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọpẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.
17 Nítorí náà Olúwa yóò mú egbòwá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”
18 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá
19 gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,
20 gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,