4 Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sìmáa jọba lóríi wọn.
5 Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́nọmọnìkejì wọn lójúẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbòsí aládùúgbò rẹ̀.Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.
6 Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọnarákùnrin rẹ̀ múnínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,“Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
7 Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,“Èmi kò ní àtúnṣe kan.Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé,ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”
8 Jérúsálẹ́mù ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́nJúdà ń ṣubú lọ,ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
9 Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù;wọn ò fi pamọ́!Ègbé ni fún wọn!Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
10 Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn.