3 Ṣùgbọ́n ààbò Fáráò yóò já sí ìtìjú fún un yín,òjìji Éjíbítì yóò mú àbùkù báa yín.
4 Bí wọ́n tilẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ ní Sóánìtí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hánísì,
5 gbogbo wọn ni a ó dójútì,nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”
6 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù:Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,ti kìnnìún àti abo kìnnìúnti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró,àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí,sí orílẹ̀ èdè aláìlérè,
7 sí Éjíbítì tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀kò wúlò rárá.Nítorí náà mo pè é níRáhábù Aláìlẹ́sẹ̀ nǹkankan.
8 Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara pátakó fún wọn,tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.
9 Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyànàti ẹlẹ́tanu ọmọ,àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí síìtọ́ni Olúwa.