1 Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Heṣekáyà, Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Júdà ó sì kó gbogbo wọn.
2 Lẹ́yìn náà, ọba Áṣíríà rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì sí ọba Hẹṣikáyà ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúsàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀,
3 Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.
4 Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Heṣekáyà,“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé: Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?