Àìsáyà 37:27-33 BMY

27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhù tuntun,gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,tí ó jóná kí ó tó dàgbà ṣókè.

28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wààti ìgbà tí o wá tí o sì lọàti bí inú rẹ ṣe ru sími.

29 Nítorí pé inú rẹ ru símiàti nítorí pé oríkunkun rẹ tidé etíìgbọ́ mi,Èmi yóò fi ìwọ mi sí ọ ní imú,àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,èmi yóò sì jẹ́ kí o padàláti ọ̀nà tí o gbà wá.

30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà:“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn.

31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́ku láti ilé Júdàyóò ta gbòǹgbò níṣàlẹ̀ yóò sì ṣo èṣo lókè.

32 Nítorí láti Jérúsálẹ́mù ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,àti láti òkè Ṣíhónì ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Ásíríà:“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wátàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ínÒun kì yóò wá síwájúu rẹ pẹ̀lú asàtàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.