30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà:“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn.
31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́ku láti ilé Júdàyóò ta gbòǹgbò níṣàlẹ̀ yóò sì ṣo èṣo lókè.
32 Nítorí láti Jérúsálẹ́mù ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,àti láti òkè Ṣíhónì ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Ásíríà:“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wátàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ínÒun kì yóò wá síwájúu rẹ pẹ̀lú asàtàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
34 Nípa ọ̀nà tí ó gbàwá náà ni yóò padà lọ;òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”ni Olúwa wí.
35 “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbàá là,nítorí mi àti nítoríì Dáfídì ìránṣẹ́ mi!”
36 Lẹ́yìn náà ni ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Ásíríà. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!