Àìsáyà 38:12-18 BMY

12 Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mini a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ọ̀ mi.Gẹ́gẹ́ bí ahunsọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13 Èmi fi ṣùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́jú,ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14 Èmi sunkún gẹ́gẹ́ bí ìṣáré tàbí ìgún,Èmi pohùnréré gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.Ìdààmú bámi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15 Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?Òun ti bá mi ṣọ̀rọ̀ àti pé òuntìkálára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ minítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.

16 Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú un wọn pẹ̀lú.Ìwọ dá ìlera mi padàkí o sì jẹ́ kí n wà láàyè

17 Nítòótọ́ fún àǹfààní mi nipé mo jẹ ìyà irú ìpọ́njú báyìí.Nínú ìfẹ́ rẹ ni o pamí mọ́kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.

18 Nítorí pé iṣà òkú kò le è yìn ọ́,ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbunkò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.