6 Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.
7 “ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fi hàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ:
8 Èmi yóò mú òjìji òòrùn kí ó padà ṣẹ́yìn ní ìsísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi ṣọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Áhásì.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn padà ṣẹ́yìn ní ìsíṣẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.
9 Ìwé tí Heṣekáyà ọba Júdà kọ lẹ́yìn àìṣàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán:
10 Èmi wí pé, “Ní àárin gbùngbùn ọjọ́ ayé mièmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikúkí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”
11 Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,àni Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;èmi kì yóò lè síjú wo ọmọnìyàn mọ́,tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ńgbe orílẹ̀ ayé báyìí.
12 Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mini a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ọ̀ mi.Gẹ́gẹ́ bí ahunsọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.