1 Ní ọjọ́ náà, obìnrin méjeyóò dì mọ́ ọkunrin kanyóò sì wí pé, “Àwa ó má a jẹ oúnjẹ ara waa ó sì pèsè aṣọ ara wa;sáà jẹ́ kí a má a fi orúkọ rẹ̀ pè wá.Mú ẹgan wá kúrò!”
2 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ogo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Ísírẹ́lì.
3 Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Síhónì, àwọn tí o kù ní Jérúsálẹ́mù, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jérúsálẹ́mù.
4 Olúwa yóò wẹ ẹgbin àwọn obinrin Síhónì kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí ìná.