2 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ogo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Ísírẹ́lì.
3 Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Síhónì, àwọn tí o kù ní Jérúsálẹ́mù, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jérúsálẹ́mù.
4 Olúwa yóò wẹ ẹgbin àwọn obinrin Síhónì kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí ìná.
5 Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sorí òkè Síhónì àti sóríi gbogbo àwọn tí ó péjọ pọ̀ ṣíbẹ̀, kúrúkúrú èéfín ní ọ̀ṣán àti ìtànsán ọ̀wọ́ iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà.
6 Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.