2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ,Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wáèmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’àti fún gúṣù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wáàti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,tí mo dá fún ògo mi,tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.