20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá,láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22 “Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,Ìwọ Jákọ́bù,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì miÌwọ Ísírẹ́lì.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan,tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhórótàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùndídùn fún mi,tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí.Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yínẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín.
25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọnàìṣedédé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn.