24 Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùndídùn fún mi,tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí.Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yínẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín.
25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọnàìṣedédé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn.
27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28 Nítorí náà, èmi yóò dójú ti àwọn ẹni àyẹ́síinú tẹ́ḿpìlìi yín,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú ìparun bá Jákọ́bùàti ìtìjú bá Ísírẹ́lì.