5 Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù;bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa,yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.
6 “Ohun tí Olúwa wí nìyìíọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun:Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan.
7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú miKí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdíàwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́?Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kanha ń bẹ lẹ́yìn mi?Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́kò jámọ́ nǹkankan.Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.
10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójú tì;àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sìfi ìdúró wọn hàn;gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.