2 Èmi yóò lọ ṣíwájú rẹèmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹṣẹÈmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹèmi ó sì gé ọ̀pá irin.
3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó farasin,Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
4 Nítorí Jákọ́bù ìránṣẹ́ miàti Ísírẹ́lì ẹni tí mo yànMo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lóríbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmìíràn;yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,Èmi yóò fún ọ ní okun,bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà oòrùntítí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùnmo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;jẹ́ kí àwọ̀sánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbàgàdà,jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;Èmi Olúwa ni ó ti dá a.