Àìsáyà 49:17-23 BMY

17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.

18 Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká;gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọwọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè,” ni Olúwa wí,“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahorotí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìgbòrò,ní ìsinsìn yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti ó jẹ ó rùn ni yóòwà ni ọ̀nà jínjìn réré.

20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹyóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’

21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?A fi èmi nìkan sílẹ̀,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22 Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí níyìí:“Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlàÈmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọnwọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrinní èjìká wọn.

23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ,àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mini a kì yóò jákulẹ̀.”