Àìsáyà 49:20-26 BMY

20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹyóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’

21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?A fi èmi nìkan sílẹ̀,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22 Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí níyìí:“Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlàÈmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọnwọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrinní èjìká wọn.

23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ,àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mini a kì yóò jákulẹ̀.”

24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?

25 Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí níyìí:“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbékùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.

26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹẹran ara wọn;wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yóbí ẹnii mu wáìnì.Nígbà náà ni gbogbo ọmọnìyàn yóò mọ̀pé Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kanṣoṣo ti Jákọ́bù.”