8 Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípòàti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
9 Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nààti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
10 Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òrùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí òòrùn kí ó pa wọ́n.Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi oríṣun omi.
11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn oke-ńlá mi di ojú-ọ̀nààti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé ṣókè.
12 Kíyèsí i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jínjìnàwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀láti ìwọ̀ oòrùn,àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Áṣíwánì.”
13 Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run;yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé;bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá!Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínúyóò sì ṣàánú fún àwọn ẹnití a ń pọ́n lójú.
14 Ṣùgbọ́n Ṣíhónì sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.”