Àìsáyà 51:11-17 BMY

11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ;ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn.Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọnìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran-ara,àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,ẹni tí ó ta àwọn ọ̀runtí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́nítorí ìbínú àwọn aninilára,tí wọ́n sì gbọ́kàn lé ipanirun?Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?

14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọwọn kò ní kú sínú túbú wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.

15 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó ń ru òkun ṣókè tó bẹ́ẹ̀ tíìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹmo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí àyè rẹ̀,ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,àti ẹni tí ó sọ fún Ṣhíónì pé,‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

17 Jí, jí!Gbéra nílẹ̀ Ìwọ Jérúsálẹ́mù,ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwakọ́ọ̀bù ìbínú rẹ̀,ìwọ tí o ti fà á mu dégẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀fèrè tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n.