1 Ta ni ó ti gba ìhìn in wa gbọ́àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?
2 Òun dàgbà ṣókè níwájúu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èhù,àti gẹ́gẹ́ bí i gbòngbo tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fàwá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́ríi rẹ̀.
3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fúna kẹ́gàn rẹ, a kò sì bọlá fún un rárá.
4 Lótìítọ́ ó ti ru àìlera wa lọó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,ṣíbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.