13 Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀Ìwà ipá yóò jìnnà sí ọo kò ní bẹ̀rù ohunkóhunÌpayà la ó mú kúrò pátapáta;kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ọ̀ mi;ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
16 “Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹtí ń fẹ́ iná èédú di èjò-inátí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan,ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀.Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”ni Olúwa wí.