3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì;ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè,wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwee rẹÌwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìwà-rópó rẹ mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ;a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
6 Olúwa yóò pè ọ́ padàà fi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀tí a sì bà lọ́kàn jẹ́obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,tí a sì wá já kulẹ̀” ni Olúwa wí.
7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóòmú ọ padà wá.
8 Ní ríru ìbínú.Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kunÈmi yóò síjú àánú wò ọ́,”ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.
9 “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà,nígbà tí mo búra pé àwọn omiNúà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.