1 “Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òrùngbẹ ń gbẹ,ẹ wá sí ibi omi;àti ẹ̀yin tí kò ní owó;ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!Ẹ wá ra wáìnì àti mílíìkìláìsí owó àti láìdíyelé.
2 Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrààti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?Tẹ́tísílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
3 Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ migbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láàyè.Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúù rẹ,ìfẹ́ Òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì.
4 Kíyèsí i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.