17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀;mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínúṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Ísírẹ́lì.Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkuntí kò le è sinmi,tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”