1 Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
3 Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi.Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀,ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi.
4 Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo;kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́;wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà