10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògirití a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;láàrin alágbára àwa dàbí òkú.
11 Gbogbo wa là ń ké bí i bíárì;àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbàA ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ̀nàfún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbérò síta.
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo ṣẹ́yìn,àti ti òdodo dúró lókèèrè;òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,òdodo kò sì le è wọlé.
15 A kò rí òtítọ́ mọ́,àti ẹni tí ó bá sá ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;nítorí apá òun tìkálárarẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,àti òdodo òun tìkálára rẹ̀ ló gbé e ró.