12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbérò síta.
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo ṣẹ́yìn,àti ti òdodo dúró lókèèrè;òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,òdodo kò sì le è wọlé.
15 A kò rí òtítọ́ mọ́,àti ẹni tí ó bá sá ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;nítorí apá òun tìkálárarẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,àti òdodo òun tìkálára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàya rẹ̀,àti àsíborí ìgbàlà ní oríi rẹ̀;ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣan ánìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;òun yóò ṣan án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.