Àìsáyà 60:10-16 BMY

10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiriì rẹ mọàwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.

11 Gbogbo ẹnu bodè rẹ ni yóò wà ní sísí sílẹ̀,a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kóọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè wátí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú níọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.

12 Nítorí pé orílẹ̀ èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;pátapáta ni yóò sì dahoro.

13 “Ògo Lẹ́bánónì yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,igi páínì, fírì àti ṣípírẹ́sì papọ̀,láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.

14 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóòwá foríbalẹ̀ fún ọ;gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹwọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú Olúwa,Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayéàti ayọ̀ àtìrandíran.

16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdèa ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.