12 Nítorí pé orílẹ̀ èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;pátapáta ni yóò sì dahoro.
13 “Ògo Lẹ́bánónì yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,igi páínì, fírì àti ṣípírẹ́sì papọ̀,láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
14 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóòwá foríbalẹ̀ fún ọ;gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹwọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú Olúwa,Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayéàti ayọ̀ àtìrandíran.
16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdèa ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.
17 Dípò búróǹsì, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,àti fàdákà dípò irun Dípò igi yóò mú búróńsì wá,àti irun dípò òkúta.Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe gómínà rẹàti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlààti àwọn ẹnu bodè rẹ ní ìyìn.