6 Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù;wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi,
7 àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmitítí tí yóò fi fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀tí yóò sì fi òun ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
8 Olúwa ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀àti nípa agbára apá rẹ:“Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹdi oúnjẹ fún ọ̀tá rẹbẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnìtuntun rẹ mọ́èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;
9 ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́tí wọn ó sì yin Olúwa,àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú unnínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”
10 Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó!Ẹ sa òkúta kúròẸ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè
11 Olúwa ti ṣe ìkédetítí dé òpin ilẹ̀ ayé:“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé,‘kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀,àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”
12 A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,ẹni ìràpadà Olúwa;a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀.