1 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.
4 Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọnń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́,tí ó rántí ọ̀nà rẹ.Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,inú bí ọ.Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,gbogbo òdodo wa sì dàbí èkíṣà ẹlẹ́gbin;gbogbo wa kákò bí ewé,àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹtàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún waó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.