10 “Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùnnínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára;Ẹ̀yin yóò mu àmuyóẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12 Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”
14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15 Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idàni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.