Àìsáyà 66:19-24 BMY

19 “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè Táṣíṣì, sí àwọn ará Líbíyà àti Lídíyà (ti a mọ̀ sí atamọ́tàsé), sí Túbálì ati ará Gíríkì, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnàréré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀ èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti wágùnnù, àti lórí ìbáaka àti ràkúnmí,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú tẹ́ḿpìlì Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.

21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Léfì,” ni Olúwa wí.

22 “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe faradà á níwájú mi,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé.

23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọnìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí.

24 “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”