2 A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ?
3 Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi?
4 Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ.
5 Ṣugbọn o ṣe! Ọlọrun iba jẹ sọ̀rọ, ki o si ya ẹnu rẹ̀ si ọ lara.
6 Ki o si fi aṣiri ọgbọ́n hàn ọ pe, o pọ̀ jù oye enia lọ; nitorina mọ̀ pe: Ọlọrun kò bere to bi ẹbi rẹ.
7 Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀?
8 O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀?