1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,
2 Ijọba ati ẹ̀ru mbẹ lọdọ rẹ̀, on ni iṣe ilaja ni ibi gigagiga rẹ̀.
3 Awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ni iye bi, tabi ara tani imọlẹ rẹ̀ kò mọ́ si?
4 Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́?
5 Kiyesi i, òṣupa kò si le itan imọlẹ, ani awọn ìrawọ kò mọlẹ li oju rẹ̀.
6 Ambọtori enia ti iṣe idin, ati ọmọ enia, ti iṣe kòkoro!