Job 41 YCE

1 IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn?

2 Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ?

3 On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ?

4 On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi?

5 Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ?

6 Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo?

7 Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja.

8 Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ.

9 Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi?

10 Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀?

11 Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni.

12 Emi kì yio fi ipin ara rẹ̀ pamọ, tabi ipá rẹ̀, tabi ihamọra rẹ̀ ti o li ẹwà.

13 Tani yio le iridi oju aṣọ apata rẹ̀, tabi tani o le isunmọ ọ̀na meji ehin rẹ̀.

14 Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla.

15 Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi,

16 Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn.

17 Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn.

18 Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ.

19 Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade.

20 Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀.

21 Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade.

22 Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀.

23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò.

24 Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.

25 Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu.

26 Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa.

27 O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù.

28 Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko.

29 O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ.

30 Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ.

31 O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra.

32 O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo.

33 Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru.

34 O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.