Job 42 YCE

1 NIGBANA ni Jobu da OLUWA lohùn o si wipe,

2 Emi mọ̀ pe, iwọ le iṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ.

3 Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye.

4 Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye.

5 Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ.

6 Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.

Ìparí

7 Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.

8 Nitorina ẹ mu akọ ẹgbọrọ malu meje, ati àgbo meje, ki ẹ si tọ̀ Jobu iranṣẹ mi lọ, ki ẹ si fi rú ẹbọ sisun fun ara nyin: Jobu iranṣẹ mi yio si gbadura fun nyin: nitoripe oju rẹ̀ ni mo gbà; ki emi ki o má ba ṣe si nyin bi iṣina nyin, niti ẹnyin kò sọ̀rọ ohun ti o tọ́ si mi bi Jobu iranṣẹ mi.

9 Bẹ̃ni Elifasi, ara Tema, ati Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama lọ, nwọn si ṣe gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: OLUWA si gbà oju Jobu.

10 OLUWA si yi igbekun Jobu pada, nigbati o gbadura fun awọn ọrẹ rẹ̀: OLUWA si busi ohun gbogbo ti Jobu ni rí ni iṣẹpo meji.

11 Nigbana ni gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o ti ṣe ojulumọ rẹ̀ rí, nwọn mba a jẹun ninu ile rẹ̀, nwọn si ṣe idaro rẹ̀, nwọn si ṣipẹ fun nitori ibí gbogbo ti OLUWA ti mu ba a: olukuluku enia pẹlu si bùn u ni ike owo-kọkan ati olukuluku ni oruka wura eti kọ̃kan.

12 Bẹ̃li OLUWA bukún igbẹhin Jobu jù iṣaju rẹ̀ lọ; o si ni ẹgba-meje agutan, ẹgba-mẹta ibakasiẹ, ati ẹgbẹrun ajaga ọda-malu, ati ẹgbẹrun abo kẹtẹkẹtẹ.

13 O si ni ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14 O si sọ orukọ akọbi ni Jemima, ati orukọ ekeji ni Kesia, ati orukọ ẹkẹta ni Keren-happuki.

15 Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn.

16 Lẹhin eyi Jobu wà li aiye li ogoje ọdun, o si ri awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ani iran mẹrin.

17 Bẹ̃ni Jobu kú, o gbó, o si kún fun ọjọ.