Job 39 YCE

1 IWỌ mọ̀ akoko igbati awọn ewurẹ ori apata ibimọ, iwọ si le ikiyesi igba ti abo-agbọnrin ibimọ?

2 Iwọ le ika iye oṣu ti nwọn npé, iwọ si mọ̀ àkoko igba ti nwọn ibi?

3 Nwọn tẹ ara wọn ba, nwọn bimọ wọn, nwọn si mu ikãnu wọn jade.

4 Awọn ọmọ wọn ri daradara, nwọn dagba ninu ọ̀dan, nwọn jade lọ, nwọn kò si tun pada wá mọ́ sọdọ wọn.

5 Tali o jọ̃ kẹtẹkẹtẹ-oko lọwọ, tabi tali o tú ide kẹtẹkẹtẹ igbẹ́?

6 Eyi ti mo fi aginju ṣe ile fun, ati ilẹ iyọ̀ ni ibugbe rẹ̀.

7 O rẹrin si ariwo ilu, bẹ̃ni on kò si gbọ́ igbe darandaran.

8 Ori àtòle oke-nla ni ibujẹ oko rẹ̀, on a si ma wá ewe tutu gbogbo ri.

9 Agbanrere ha jẹ sìn ọ bi, tabi o jẹ duro ni ibujẹ ẹran rẹ?

10 Iwọ le ifi kátà dè agbanrere ninu aporo, tabi o jẹ ma fà itulẹ ninu aporo oko tọ̀ ọ lẹhin?

11 Iwọ o gbẹkẹlẹ e, nitori agbara rẹ̀ pọ̀, iwọ o si fi iṣẹ rẹ le e li ọwọ?

12 Iwọ le igbẹkẹle e pe, yio mu eso oko rẹ wá sile; pe, yio si ko o jọ sinu àka rẹ̀?

13 Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi?

14 Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru.

15 Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ:

16 Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru:

17 Nitoripe Ọlọrun dù u li ọgbọ́n, bẹ̃ni kò si fi ipin oye fun u.

18 Nigbati o gbe ara soke, o gàn ẹṣin ati ẹlẹṣin.

19 Iwọ li o fi agbara fun ẹṣin, iwọ li o fi gọ̀gọ wọ ọrùn rẹ̀ li aṣọ?

20 Iwọ le imu u fò soke bi ẹlẹnga, ogo ẽmi imu rẹ̀ ni ẹ̀ru-nla.

21 O fi ẹsẹ halẹ ninu aporo, o si yọ̀ si agbara rẹ̀; o nlọ jade lati pade awọn ahamọra ogun.

22 O fi oju kekere wò ẹ̀ru, aiya kò si fò o; bẹ̃ni kì isi ipada sẹhin kuro lọwọ idà.

23 Lọdọ rẹ̀ ni apo-ọfa nmi pẹkẹpẹkẹ, ati ọ̀kọ didan ati apata.

24 On fi kikoro oju ati ibinu nla gbe ilẹ mì, bẹ̃li on kò si gbagbọ pe, iro ipè ni.

25 O wi ni igba ipè pe, Ha! Ha! o si gborùn ogun lokere rere: ãrá awọn balogun ati ihó àyọ wọn.

26 Awodi a ma ti ipa ọgbọ́n rẹ fò soke, ti o si nà iyẹ apa rẹ̀ siha gusu?

27 Idì a ma fi aṣẹ rẹ fò lọ soke, ki o si lọ itẹ ìtẹ rẹ̀ si oke giga?

28 O ngbe o si wọ̀ li ori apata, lori palapala okuta ati ibi ori oke.

29 Lati ibẹ lọ ni ima wá ọdẹ kiri, oju rẹ̀ si riran li òkere rere.

30 Awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu a ma mu ẹ̀jẹ, nibiti okú ba gbe wà, nibẹ li on wà pẹlu.