1 NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
2 Ọlọgbọ́n a ma sọ̀rọ ìmọ asan, ki o si ma fi afẹfẹ ila õrùn kún ara rẹ̀ ninu:
3 On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere?
4 Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun.
5 Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò.
6 Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ.
7 Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke?
8 Iwọ gburo aṣiri Ọlọrun ri, tabi iwọ ha dá ọgbọ́n duro sọdọ ara rẹ?
9 Kini iwọ mọ̀ ti awa kò mọ̀, oye kili o ye ọ ti kò si ninu wa.
10 Elewú ogbó ati ògbologbo enia wà pẹlu wa, ti nwọn gbó jù baba rẹ lọ.
11 Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ.
12 Ẽṣe ti aiya rẹ fi ndà ọ kiri, tabi kini iwọ tẹjumọ wofin.
13 Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃?
14 Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo?
15 Kiyesi i, on (Ọlọrun) kò gbẹkẹle awọn ẹni-mimọ́ rẹ̀, ani awọn ọrun kò mọ́ li oju rẹ̀.
16 Ambọtori enia, ẹni irira ati elẽri, ti nmu ẹ̀ṣẹ bi ẹni mu omi.
17 Emi o fi hàn ọ, gbọ́ ti emi, eyi ti emi si ri, on li emi o si sọ.
18 Ti awọn ọlọgbọ́n ti pa ni ìtan lati ọdọ awọn baba wọn wá, ti nwọn kò si fi pamọ́.
19 Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja.
20 Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara.
21 Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i.
22 O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà.
23 O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi.
24 Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun.
25 Nitoripe o ti nawọ rẹ̀ jade lodi si Ọlọrun, o si mura rẹ̀ le lodi si Olodumare.
26 O sure, o si fi ẹhin giga kọlu u, ani fi ike-koko apata rẹ̀ ti o nipọn.
27 Nitoriti on fi ọra rẹ̀ bo ara rẹ̀ loju, o si ṣe jabajába ọra si ẹgbẹ rẹ̀.
28 On si gbe inu ahoro ilu itakété, ati ninu ileyile ti enia kò gbe mọ́, ti o mura tan lati di àlapa.
29 On kò le ilà, bẹ̃ni ohun ini rẹ̀ kò le iduro pẹ, bẹ̃ni kò le imu pipé rẹ̀ duro pẹ lori aiye.
30 On kì yio jade kuro ninu okunkun, ọ̀wọ-iná ni yio jo ẹká rẹ̀, ati nipasẹ ẹmi ẹnu rẹ̀ ni yio ma kọja lọ kuro.
31 Ki on ki o má ṣe gbẹkẹle asan, o tan ara rẹ̀ jẹ; nitoripe asan ni yio jasi ère rẹ̀.
32 A o mu u ṣẹ ṣaju pipe ọjọ rẹ̀, ẹka rẹ̀ kì yio si tutu.
33 Yio si gbòn talubọ eso rẹ̀ dànu bi àjara, yio si rẹ̀ itana rẹ̀ nù bi ti igi olifi.
34 Nitoripe ajọ awọn àgabagebe yio tuka, iná ni yio si jo agọ abẹtẹlẹ.
35 Nwọn loyun ìwa-ika, nwọn si bi ẹ̀ṣẹ, ikùn wọn si pèse ẹ̀tan.