1 AGARA ìwa aiye mi da mi tan, emi o tú aroye mi sode lọdọ mi, emi o ma sọ ninu kikorò ibinujẹ ọkàn mi.
2 Emi o wi fun Ọlọrun pe, o jare! máṣe dá mi lẹbi; fi hàn mi nitori idi ohun ti iwọ fi mba mi jà.
3 O ha tọ́ si ọ ti iwọ iba ma tẹ̀mọlẹ̀, ti iwọ iba fi ma gan iṣẹ ọwọ rẹ, ti iwọ o fi ma tan imọlẹ si ìmọ enia buburu?
4 Oju rẹ iha ṣe oju enia bi? tabi iwọ a ma riran bi enia ti iriran?
5 Ọjọ rẹ ha dabi ọjọ enia, ọdun rẹ ha dabi ọdun enia?
6 Ti iwọ fi mbere aiṣedẽde mi, ti iwọ si fi wa ẹ̀ṣẹ mi ri?
7 Iwọ mọ̀ pe emi kì iṣe oniwa-buburu, kò si sí ẹniti igbà kuro li ọwọ rẹ.
8 Ọwọ rẹ li o ti dá mi, ti o si mọ mi pọ̀ yikakiri; sibẹ iwọ si mbà mi jẹ́.
9 Emi bẹ̀ ọ ranti pe iwọ ti mọ mi bi amọ̀; iwọ o ha si tun mu mi pada lọ sinu erupẹ?
10 Iwọ kò ha ti tu mi dà jade bi wàra, iwọ kò si mu mi dipọ̀ bi wàrakasi?
11 Iwọ sa ti fi awọ ati ẹran-ara wọ̀ mi, iwọ si fi egungun ati iṣan ṣọgbà yi mi ká.
12 Iwọ ti fun mi li ẹmi ati oju rere, ibẹ̀wo rẹ si pa ọkàn mi mọ́.
13 Nkan wọnyi ni iwọ si ti fi pamọ ninu rẹ; emi mọ̀ pe, eyi mbẹ lọdọ rẹ.
14 Bi mo ba ṣẹ̀, nigbana ni iwọ sàmi si mi, iwọ kì yio si dari aiṣedede mi ji.
15 Bi mo ba ṣe ẹni-buburu, egbé ni fun mi! bi mo ba si ṣe ẹni-rere, bẹ̃li emi kò si le igbe ori mi soke. Emi damu, mo si wo ipọnju mi.
16 Nitoriti npọ̀ si i: iwọ ndẹ mi kiri bi kiniun; ati pẹlu, iwọ a si fi ara rẹ hàn fun mi ni iyanju.
17 Iwọ si tun sọ awọn ẹlẹri rẹ si mi di ọtun, iwọ si sọ irunu rẹ di pipọ si mi, ayipada ati ogun dó tì mi.
18 Njẹ nitorina iwọ ha ṣe bí mi jade lati inu wá? A! emi iba kúku ti kú, ojukoju kì ba ti ri mi!
19 Emi iba dabi ẹniti kò si ri, a ba ti gbe mi lati inu lọ si isà-okú.
20 Ọjọ mi kò ha kuru bi? dawọ duro, ki o si jọwọ mi jẹ ki emi fi aiya balẹ diẹ.
21 Ki emi ki o to lọ sibi ti emi kì yio pada sẹhin mọ́, ani si ilẹ òkunkun ati ojiji ikú.
22 Ilẹ òkunkun bi òkunkun tikararẹ̀, ati ti ojiji ikú, laini èto, nibiti imọlẹ dabi òkunkun.