Job 8 YCE

1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,

2 Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla?

3 Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi?

4 Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn.

5 Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare.

6 Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ.

7 Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi.

8 Emi bẹ̀ ọ njẹ, bere lọwọ awọn ara igbãni, ki o si kiyesi iwádi awọn baba wọn.

9 Nitoripe ọmọ-àná li awa, a kò si mọ̀ nkan, nitoripe òjiji li ọjọ wa li aiye.

10 Awọn kì yio ha kọ́ ọ, nwọn kì yio si sọ fun ọ, nwọn kì yio si sọ̀rọ lati inu ọkàn wọn jade wá?

11 Koriko odò ha le dàgba laini ẹrẹ̀, tabi ẽsú ha le dàgba lailomi?

12 Nigbati o wà ni tutù, ti a kò ke e lulẹ̀, o rọ danu sin eweko miran gbogbo.

13 Bẹ̃ni ipa ọ̀na gbogbo awọn ti o gbagbe Ọlọrun, abá awọn àgabàgebe yio di ofo.

14 Abá ẹniti a o ke kuro, ati igbẹkẹle ẹniti o dàbi ile alantakùn.

15 Yio fi ara tì ile rẹ̀, ṣugbọn kì yio le iduro, yio fi di ara rẹ̀ mu ṣinṣin ṣugbọn kì yio le iduro pẹ.

16 O tutù niwaju õrùn, ẹka rẹ̀ si yọ jade ninu ọgbà rẹ̀.

17 Gbòngbo rẹ̀ ta yi ebè ka, o si wò ibi okuta wọnni.

18 Bi o ba si pa a run kuro ni ipò rẹ̀, nigbana ni ipò na yio sẹ ẹ pe: emi kò ri ọ ri!

19 Kiyesi eyi ni ayọ̀ ọ̀na rẹ̀ ati lati inu ilẹ li omiran yio ti hù jade wá.

20 Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ.

21 Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀.

22 Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.