Job 1 YCE

Satani Dán Jobu Wò

1 ỌKUNRIN kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹniti ijẹ Jobu; ọkunrin na si ṣe olõtọ, o duro ṣinṣin, ẹniti o si bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.

2 A si bi ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta fun u.

3 Ohunọ̀sin rẹ̀ si jẹ ẹdẹgbarin agutan, ati ẹgbẹdogun ibakasiẹ, ati ẹdẹgbẹta ajaga ọdámalu, ati ẹdẹgbẹta abokẹtẹkẹtẹ, o si pọ̀; bẹ̃li ọkunrin yi si pọ̀ jù gbogbo awọn ọmọ ara ila-õrun lọ.

4 Awọn ọmọ rẹ̀ a si ma lọ ijẹun àse ninu ile ara wọn, olukuluku li ọjọ rẹ̀; nwọn a si ma ranṣẹ pe arabinrin wọn mẹtẹta lati jẹun ati lati mu pẹlu wọn.

5 O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo.

6 Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn.

7 Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.

8 Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.

9 Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi?

10 Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ.

11 Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.

12 Oluwa si dá Satani lohùn wipe: kiyesi i, ohun gbogbo ti o ni mbẹ ni ikawọ rẹ, kìki on tikara rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ rẹ kàn: bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa.

Ọrọ̀ ati Àwọn Ọmọ Jobu Parun

13 O si di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati obinrin njẹ, ti nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin:

14 Onṣẹ kan si tọ̀ Jobu wá wipe: awọn ọda-malu ntulẹ, awọn kẹtẹkẹtẹ si njẹ li ẹba wọn;

15 Awọn ara Saba si kọlu wọn, nwọn si nkó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn ti fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa, emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati ròhin fun ọ.

16 Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ.

17 Bi o si ti nsọ li ẹnu, ẹnikan si de pẹlu ti o wipe: awọn ara Kaldea pingun si ọ̀na mẹta, nwọn si kọlu awọn ibakasiẹ, nwọn si kó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn si fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa; emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati rohin fun ọ.

18 Bi o ti nsọ li ẹnu, ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin njẹ nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin.

19 Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ.

20 Nigbana ni Jobu dide, o si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, o si fari rẹ̀, o wolẹ, o si gbadura.

21 Wipe, Nihoho ni mo ti inu iya mi jade wá, nihoho ni emi o si tun pada lọ sibẹ: Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa.

22 Ninu gbogbo eyi Jobu kò ṣẹ̀, bẹ̃ni kò si fi were pè Ọlọrun lẹjọ.