Job 37 YCE

1 AIYA si fò mi si eyi pẹlu, o si ṣi kuro ni ipò rẹ̀.

2 Fetisilẹ dãda, ki ẹ si gbọ́ iró ohùn rẹ̀, ati iró ti o ti ẹnu rẹ̀ jade wá.

3 O ṣe ilana rẹ̀ nisalẹ abẹ ọrun gbogbo, manamana rẹ̀ ni o si jọwọ rẹ̀ lọwọ de opin ilẹ aiye.

4 Lẹhin manamana ohùn kan fọ̀ ramuramu, o fi ohùn ọlanla rẹ̀ sán ãrá: on kì yio si da ãrá duro nigbati a ba ngbọ́ ohùn rẹ̀.

5 Ọlọrun fi ohùn rẹ̀ sán ãrá iyanilẹnu, ohun nlanla ni iṣe ti awa kò le imọ̀.

6 Nitoriti o wi fun ojo didì pe, Iwọ rọ̀ silẹ aiye, ati pẹlu fun ọwọ ojo, ati fun ojo nla agbara rẹ̀.

7 O fi edidi di gbogbo enia, ki gbogbo wọn ki o le imọ̀ iṣẹ rẹ̀.

8 Nigbana ni awọn ẹranko iwọnu ihò lọ, nwọn a si wà ni ipò wọn.

9 Lati iha gusu ni ìji ajayika ti ijade wá, ati otutu lati inu afẹfẹ ti tu awọsanma ká.

10 Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì.

11 Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká.

12 Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ.

13 O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu.

14 Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun.

15 Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán?

16 Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ?

17 Aṣọ rẹ̀ ti ma gbona, nigbati o mu aiye dakẹ lati gusu wá.

18 Iwọ ha ba a tẹ pẹpẹ oju-ọrun, ti o duro ṣinṣin, ti o si dabi digi ti o yọ́ dà.

19 Kọ́ wa li eyi ti a le iwi fun u; nitoripe awa kò le iladi ọ̀rọ nitori òkunkun.

20 A o ha wi fun u pe, Emi fẹ sọ̀rọ? tabi ẹnikan wipe, Ifẹ mi ni pe ki a gbe mi mì?

21 Sibẹ nisisiyi enia kò ri imọlẹ ti ndán ninu awọsanma, ṣugbọn afẹfẹ kọja, a si gbá wọn mọ́.

22 Wura didan ti inu iha ariwa jade wá, lọdọ Ọlọrun li ọlanla ẹ̀ru-nla.

23 Nipa ti Olodumare awa kò le iwadi rẹ̀ ri, o rekọja ni ipá, on kì iba idajọ ati ọ̀pọlọpọ otitọ jẹ.

24 Nitorina enia a ma bẹ̀ru rẹ̀, on kì iṣojusaju ẹnikẹni ti o gbọ́n ni inu.