1 NIGBANA ni Jobu si dahùn wipe,
2 Ani loni ni ọ̀ran mi korò; ọwọ mi si wuwo si ikerora mi.
3 A! emi iba mọ̀ ibi ti emi iba wá Ọlọrun ri! ki emi ki o tọ̀ ọ lọ si ibujoko rẹ̀,
4 Emi iba si tò ọran na niwaju rẹ̀, ẹnu mi iba si kún fun aroye.
5 Emi iba si mọ̀ ọ̀rọ ti on iba fi da mi lohùn, oye ohun ti iba wi a si ye mi.
6 Yio ha fi agbara nla ba mi wijọ bi? agbẹdọ̀! kiki on o si kiyesi mi:
7 Nibẹ li olododo le iba a wijọ, bẹ̃li emi o si bọ́ li ọwọ onidajọ mi lailai.
8 Si wò! bi emi ba lọ si iha ila-õrùn, on kò si nibẹ, ati si iwọ-õrùn ni, emi kò si roye rẹ̀:
9 Niha ariwa bi o ba ṣiṣẹ nibẹ, emi kò ri i, o fi ara rẹ̀ pamọ niha gusu, ti emi kò le ri i.
10 Ṣugbọn on mọ̀ ọ̀na ti emi ntọ̀, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura.
11 Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọ̀na rẹ̀ ni mo ti kiyesi, ti nkò si yà kuro.
12 Bẹ̃ni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ̀, emi si pa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ mọ́ jù ofin inu mi lọ.
13 Ṣugbọn oninukan li on, tani yio si yi i pada? Eyiti ọkàn rẹ̀ si ti fẹ, eyi na ni iṣe.
14 Nitõtọ ohun ti ati yàn silẹ fun mi ni nṣe, ọ̀pọlọpọ iru bẹ li o wà li ọwọ rẹ̀.
15 Nitorina ni ara ko ṣe rọ̀ mi niwaju rẹ̀, nigbati mo ba rò o, ẹ̀ru a ba mi.
16 Nitoripe Ọlọrun ti pá mi li aiya, Olodumare si ndamu mi.
17 Nitoriti a kò ti ke mi kuro niwaju òkunkun, bẹ̃ni kò pa òkùnkùn-biribiri mọ kuro niwaju mi.