1 Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e.
2 Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin.
3 Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye.
4 Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin.
5 O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin.
6 Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi.
7 Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e?
8 Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun?
9 O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji.
10 Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ.
11 Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya?
12 Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀.
13 Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀.
14 Njẹ nitori kili emi ṣe nfi ehin mi bù ẹran ara mi jẹ, ti mo si gbe ẹmi mi le ara mi lọwọ?
15 Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e, ṣugbọn emi o ma tẹnumọ ọ̀na mi niwaju rẹ̀.
16 Eyi ni yio si ṣe igbala mi pe: àgabagebe kì yio wá siwaju rẹ̀.
17 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi ni ifaiyabalẹ, ati asọpe mi li eti nyin.
18 Wò o nisisiyi emi ti ladi ọ̀ran mi silẹ; emi mọ̀ pe a ó da mi lare.
19 Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ.
20 Ṣugbọn ọkan ni, máṣe ṣe ohun meji yi si mi, nigbana ni emi kì yio si fi ara mi pamọ, kuro fun ọ,
21 Fa ọwọ rẹ sẹhin kuro lara mi; má si jẹ ki ẹ̀ru rẹ ki o pá mi laiya.
22 Nigbana ni ki iwọ ki o pè, emi o si dahùn, tabi jẹ ki nma sọ̀rọ, ki iwọ ki o si da mi lohùn.
23 Melo li aiṣedede ati ẹ̀ṣẹ mi, mu mi mọ̀ irekọja ati ẹ̀ṣẹ mi!
24 Nitori kini iwọ ṣe pa oju rẹ mọ́, ti o si yàn mi li ọta rẹ?
25 Iwọ o fa ewe ya ti afẹfẹ nfẹ sihin sọhun: iwọ a si ma lepa akemọlẹ poroporo gbigbẹ!
26 Nitoripe iwọ kọwe ohun kikoro si mi, o si mu mi ni aiṣedede ewe mi.
27 Iwọ kàn àba mọ mi lẹsẹ pẹlu, iwọ si nwò ipa ọ̀na irin mi li awofin, iwọ si nfi ãlà yi gigisẹ mi ka.
28 Ani, yi ẹniti a ti run ka, bi ohun ti o bu, bi aṣọ ti kòkoro jẹ bajẹ.